Oruko Iyanu Re · ÷
oniwaasu chris
Jesu si wa, o si so fun won, wipe, gbogbo agbara li orun ati li aye li a fi fun mi. Nitori naa e lo, e maa ko orile-ede gbogbo, ki e si maa baptisi won li oruko Baba, ati ni ti Omo, ati ni ti Emi Mimo: ki e maa ko won lati maa kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li ase fun nyin… (Mattheu 28:18-20).
Oro naa fihan wa wipe Jesu fi gbogbo agbara ati ase Re fun wa, O si oase fun wa lati waasu Ihinrere naa fun gbogbo aye, ni Oruko Oun. O wipe, "…ki e si maa baptisi won li oruko ti Baba, ati ni ti Omo, ati ni ti Emi Mimo." Se akiyesi wipe Oruko Jesu ni Oruko Baba, Omo, ati Emi Mimo nje. Bi o ba se ayewo ninu iwe Ise Awon Aposteli, awon Aposteli baptisi ni oruko Jesu (Ise 2:38, 8:16, 10:48, 19:5, 22:16). Won ni oye awon oro Jesu laise ani-ani. Won mo wipe oruko Jesu ni oruko Metalokan! Bi o ba wipe "ni oruko Jesu," o nso nipa awon meteeta.
Kolosse 1:19 wipe, "Nitori didun inu Baba nip e, ki ekun gbogbo le ma gbe inu re (Jesu)." Ninu Jesu ni ekun gbogbo ngbe—oruko ti o ju gbogbo oruko lo. Je ki oruko Jesu maa wu o lori! Fillipi 2:10 wipe "…pe ni oruko Jesu ni ki gbogbo eekun ki o maa kunle, awon eniti mbe ni orun, ati awon eniti mbe ni ile, ati awon eniti mbe nisale ile." Ohun gbogbo ti mbe ni orun, ni isale ile ati ni abe ile ni o gbodo teriba fun Jesu.
Ijewo Baba mi owon, mo dupe pe O funmi l’ase lati maa lo Oruko Jesu! Mo ngbe nipa agbara ti mbe ninu Oruko naa loni, pelu isegun ati ododo. Mo nri alaafia, ilosiwaju, alekun, aseyori ati opolopo ibukun nigbagbogbo, ni Oruko Jesu. Amin.
÷kë kíkà siwaju: Luku 10:19; Fillipi. 2:9-11
BIBELI KIKA LÓÒNI
Èètò fun Kîka Bibeli já Lodún Kan : II Timoteu 1:1-18, Isaiah 64-66Èètò fun Kîka Bibeli já Lodún Méjì : Johannu 7:32-44 II. Awön ëba 13-14
No comments:
Post a Comment