Thursday, 24 October 2013

(in yoruba lang) RHAPSODY OF REALITIES .ọjọbọ, Ọwara 24

Aabo Re Daju Ninu Rè! ·

O ngba ni, O si nyo ni, o si nse ise-ami ati ise-iyanu li orun ati li aye, eniti o gba Danieli la lowo awon kiniun (Danieli 6:27).
Pastor Anita oniwaasu anita
 Oluwa ni olugbala ati oludande; O ngba olododo kuro ninu iponju ati kuro ninu iparun. Orin 59:16 wipe, "Sugbon emi o korin agbara re; nitooto, emi o korin aanu re kikan li owuro: nitori pe iwo li o ti nse abo ati ibi-asala mi li ojo iponju mi." Oun ni ibi-abo ti o daju. Bi o ba ti di atunbi, inu Re ni iwo ngbe; emi re pamo sinu Kristi ninu Olorun (Kolosse 3:3). Kristi ni ibi-asala re, Oun si ni aabo re. Abajo ti O fi gba wa niyaju ni opolopo igba wipe ki a "mase beru."
Ko si ohunkohun tabi enikeni ti iba doju ija ko o; Oluwa wipe, "mase beru." Mase beru awon ota, ki o ma si s’ojo bi won iba tit obi to. Je alagbara ninu Oluwa, ati ninu ipa Re (Efesu 6:10). Iwo nikan ko ni o da wa. Bibeli so ninu Heberu 12:22, "Sugbon enyin wa si oke Sioni, ati si ilu Olorun alaaye, ti Jerusalemu ti orun, ati si egbe angeli ainiye…" Awon angeli yi o ka lopolopo, a si ti fun won ni ase lati pa o mo, ki won si maa daabo bo o ni gbogbo ona re (Orin 91:11).
1 Johannu 4:4 wipe, "Enyin omo mi, ti Olorun li enyin, enyin si ti segun won: nitori eniti mbe ninu nyin ju eniti mbe ninu aye lo." Iwo ti segun ota. Mase fetisi ohunkohun ti o ban je ki o dabi enipe ota lagbara. Ona ti iberu se maa ngbile niyi. Dipo bee, fi oro igbagbo gbe okan re ro. Maa fetisi oro ti o kun fun igbagbo nigba gbogbo, titi ti iberu ki yio fi ri aaye ninu emi re.
Gba Oro Olorun fun o l’oni; se ijewo pelu igboya wipe Kristi ni odi ati aabo re! ninu Re ni iwo ngbe, ti o nrin, ti iseda re si ti jade wa; nitorinaa, ko si ohun-ibi kan ti yio sele si o! Orin 91:7 wipe, "Egberun yio subu ni egbei re, ati egbaarun ni apa otun re; sugbon ki yio sunmo odo re." Inu Re ni iwo ngbe; nitorinaa, aabo re daju, a si ti ko o yo kuro ninu iponju, ewu, ijakule ati iku. "Iwo ki yio beru nitori eru oru; tabi fun ofa t info li osan" (Orin 91:5).
Ijewo  Mo pase pe mo ni isegun ati ogo ninu Kristi Jesu. Mo nrin ninu ogbon ati pelu agbara ti Emi l’oni; nitoripe gbigbega ni eniti ngbe ninu mi, ju eniti ngbe ninu aye lo. Emi ju asegun lo.
÷kë kíkà siwaju: Orin 32:7; Orin 91:1-16

BIBELI KIKA LÓÒNI

Èètò fun Kîka Bibeli já Lodún Kan : I.Timoteu 6:1-21, Isaiah 61-63
Èètò fun Kîka Bibeli já Lodún Méjì : Johannu 7:20-31, II. Awön ëba 11-12

No comments:

Post a Comment